ÈKÌTÌ KỌ̀YÀ

Ìpínlẹ̀ Èkìtì ń ṣòjòjò ó sì nílò àtúnṣe ní kíákíá. Àkọsílẹ̀ ẹ̀ka àṣẹ ìjọba àpapọ̀ nípa ìṣíye tí a mọ̀ sí National Bureau of Statistics (NBS) fi hàn pé àwọn ọ̀dọ́ tí kò níṣẹ́ lọ́wọ́ ní Ìpínlẹ̀ Èkìtì jẹ́ ìdáméjìlélọ́gbọ̀n lé pẹ́sẹ́pẹ́sẹ́ nínú ìdá ọ̀gọ́rùn-ún àwọn ọ̀dọ́ tó yẹ kó wà lẹ́nu iṣẹ́, tí iye àwọn tojú ń pọ́n náà sì kọjá ìlàjì gbèdéke òṣùwọ̀n ìjọba àpapọ̀. Pẹ̀lú ìlànà ìṣúná oní ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù náírà ó lé mẹ́jọ (N100.8 billion) yìí, àwa ni a ní owó ìṣúná tí ó kéré jùlọ nínú gbogbo Ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì pẹ̀lú u pé a ní Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ohun àlùmọ́ọ́nì àti àwọn ènìyàn pàtàkì, èyí tí ó fi hàn pé ìjọba tó wà lórí àga ìṣàkóso báyìí kò ní agbára àrògún láti gbé ìlànà ìpawó wọlé lábẹ́lé kalẹ̀ fún ìdàgbàsókè Ìpínlẹ̀.

Ohun mìíràn tí ó tún bani nínú jẹ́ ni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó oṣù, owó àjẹmọ́nú àti owó ìfẹ̀yìntì tó tọ́ sí àwọn tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ àṣekára ni wọn kì í san bó ti tọ́.

Kò sí ààbò ní tìbú-tòòró Ìpínlẹ̀ èyí sì ti ṣe àkóbá tó pọ̀ fún ìdàgbàsókè okòwò wa, ní pàápàá jùlọ ẹ̀ka iṣẹ́ ọ̀gbìn àti ìrìn-àjò a fẹ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àgbẹ̀ wa ni wọ́n ti sá kúrò lórí oko wọn tí ọ̀pọ̀ àwọn ibi ìgbà fẹ́ wa náà ti dẹnukọlẹ̀ ńítorí gbọnmọgbọnmọ àìsí ààbò. Àkójọpọ gbèsè tí Ìpínlẹ̀ jẹ sí ẹ̀ka tí ń ṣàkóso ètò ìsúná ti jẹ́bílíọ̀nù mẹ́ta lé lọ́gọ́fà ó lé lẹ́gbẹ̀rún méjì dín láàádọ́rùn-ún náírà bayìí (N123.88b) èyí sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn gbèsè tí ó pọ̀ jùlọ lórílẹ̀-èdè. Èyí tí ó burú jù, tí ó sì ka ni láyà láti kíyèsí ni àìbìkítà ìṣèjọba tó ń tukọ̀ Ìpínlẹ̀ yìí lọ́wọ́ láti tún ṣètò Ìyáwó láti ìta fún ọdún márùn-ún-dín-lọ́gbọ̀n gbáko láì fi owó kankan pamọ́ fún àwọn ìran tó ń bọ̀ ní Ìpínlẹ̀ Èkìtì.

Ó yẹ kí á yan aṣáájú tí ó kájúẹ̀ tí a finú tán tí ó ka àwọn ènìyàn Èkìtì sí pàtàkì, tí yóò sì máa fìgbà gbogbo pa ìfẹ́ wọn mọ́ láti tún Ìpínlẹ̀ wa ọ̀wọ́n ṣe ní kíákíá. A kò nílò àwọn olórí tí wọ́n kàn fẹ́ gbé orúkọ oyè lérí tí wọn ó sì máa di ẹ̀bi ru àwọn ará ìlú. A nílò olórí tí ó mọ̀ pé ohun tí jíjáwé olúborí nínú ètò Ìdìbò túmọ̀ sí ni pé gbogbo àwọn ènìyàn Èkìtì tí yọ̀ǹda agbára wọn fún olórí bẹ́ẹ̀ nínú ìfọkàntán pé  olórí náà yóò máa lò ó fún Ìlọsíwájú wọn nínú ohun gbogbo. Èyí ni ìlànà ìdarí tí mo mú lọ́kùn-únkúndùn ṣáájú, tí màá sì tún ṣe Lẹ́ẹ̀kan sí i bí ẹ bá dìbò yàn mí.

Ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kẹfà ọdún yìí ni wọ́n ti là kalẹ̀ fún ìdìbò sí ipò gómìnà fún Ìpínlẹ̀ Èkìtì.

Ẹ rántí pé àwọn tí wọ́n gbé Ìpínlẹ̀ yìí dé ìpele ìṣubú yìí rẹ́sẹ̀walẹ̀ nínú àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú tó lààmì laaka ní Ìpínlẹ̀ pẹ̀lú èrò láti wà ní ipò agbára nípasẹ̀ àwọn abẹ́ṣinkáwọ́ wọn. Ó tiẹ̀ fẹ́ẹ́ má ṣeé ṣe fún ẹni tí kò bá tẹríba fún wọn láti jáwé olú borí nínú àwọn Ìdìbò abẹ́lé láti yan olùdíje nínú àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú wọ̀nyí. Ó ṣeni láàánú pé àwọn ènìyàn Èkìtì ti fàyè gbà ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n fún sáà méjì láti ṣe àfihàn ara wọn nínú èyí tí wọ́n ti kùnà, ọ̀nà kan ṣoṣo tí wọ́n sì leè gbà daṣọ bo ìkùnà wọn ni kí wọn ó má kúrò ní ipò àṣẹ nípasẹ̀ àwọn àsọmọgbe wọn, èyí tí wọn ó kì babẹ́ láti má jẹ́ kóhun tí wọ́n ti ṣe ó déta. Àsìkò yìí ni ó tọ́ láti korò ojú, kí á sì dìde, kí á sowọ́pọ̀ láti gba ominira wa papọ̀. Ìpè sí iṣẹ́ pàtàkì ni èyí.

Mò ń fi ara mi fún un yín pẹ̀lú ọkàn ìrẹ̀lẹ̀ àti ìpinnu láti ṣiṣẹ́ sin ẹ̀yin ènìyàn Ìpínlẹ̀ Èkìtì pẹ̀lú àbájáde tó kẹ́sẹjárí. Mo sanwó oṣù òṣìṣẹ́ lásìkò tó tọ́, àwọn ọ̀nà tí mo ṣe pọ̀ ju ti àwọn gómìnà yòókù lọ, n ò sì jẹ gbèsè kankan.

 Àkọsílẹ̀ àjọ tó ń rí sí ìdàgbàsókè ọmọnìyàn tí a mọ̀ sí UNDP ti ọdún 2009 kéde pé ipò kẹwàá ni Ìpínlẹ̀ Èkìtì wáà nínú Ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì tó wà lórílẹ̀ èdè yìí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò kẹrìnlélọ́gbọ̀n ló wà nínú ìlànà ìpínwó olóṣooṣù ti ìjọba àpapọ̀ àti ìkẹrìnlélógún nínú ìdókòòwò ilẹ̀ òkèèrè. Èyí fi hàn kedere bí a ti fi ọgbọ́n àti ìmọ̀ọ́ṣe lo owó perete tó wọlé sí àkàtà mi. Ó tún yani lẹnu láti gbọ́ pé Ìpínlẹ̀ Èkìtì gbégbá orókè fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìrètí ní orílẹ̀-èdè. Láàrin àsìkò náà, gbogbo ènìyàn ní Ìpínlẹ̀ Èkìtì ni ayé dáa tí ó sì ní ìtumọ̀ fún. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, Mò ń fọwọ́ sọ̀yà pé n ò jí owó yín. Mo sìn yín pẹ̀lú ìfẹ́ àti òtítọ́ inú.

Mo ṣe tán láti sin Ìpínlẹ̀ Èkìtì Lẹ́ẹ̀kan sí i ṣùgbọ́n mo kọ́kọ́ gbọdọ̀ jáwé olúborí nínú Ìdìbò ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kẹfà ọdún 2022. Mo nílò gbogbo àwọn ìbò àti ìrànlọ́wọ́ yín.

Èmi àti àwọn aṣáájú pàtàkì mìíràn tí a ní èrò kan náà ti lọ sínú ẹgbẹ́ òṣèlú Social Democratic Party (SDP) láti fi òpin sí ìwà taa ni yóò mú mi èyí tí àwọn tí wọ́n ti já wa kulẹ̀ tí wọ́n sì tún fẹ́ fi Ìpínlẹ̀ yìí sábẹ́ wọn nípa yíyan ọmọ-oyè fún wa. Láti fún ìpolongo wa lágbára láti yẹ àga mọ́ àwọn Olóṣèlú wọ̀nyí àti àwọn àsọmọgbè wọn nídìí nílò owó tí ó tówó, níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fi ẹgbẹ́ òṣèlú titun lọ́lẹ̀ ni. A ní láti ṣiṣẹ́ kárakára pẹ̀lú ìjáfáfá àti ìsowọ́pọ̀ nínú ètò Ìdìbò tó ń bọ̀ kí á má ba à kó sínú páńpẹ́ owó òṣèlú wọn. Lásìkò yìí, àwọn ènìyàn Èkìtì gbọ́dọ̀ gba Ìpínlẹ̀ wọn kí wọn ó sì dá ìwà tí ó tọ́, òdodo àti ìlànà gbangba làsá-ń-ta padà kí á baà le tún sọ ohun tí ó dára di àṣà wa lẹ́ẹ̀kan sí i ní Ìpínlẹ̀ Èkìtì.

Ọ̀kan wa balẹ̀ pé a le è dojú wọn bolẹ̀ lásìkò Ìdìbò kí á sì dá Ìpínlẹ̀ padà fún àwọn ọmọ Ìpínlẹ̀ Èkìtì, ṣùgbọ́n a nílò ẹ̀yin àti ìrànlọ́wọ́ yín láti jẹ́ kí iṣẹ́ yìí ó ṣe é ṣe.

A ti ṣe ìfilọ́lọ̀ ìpolongo ìdáwójọ láti ràn wá lọ́wọ́ láti kó owó jọ kí ìpolongo wa ó ba à le kẹ́sẹjárí fún àbájáde àṣeyọrí. Ilé-iṣẹ́ tó ń bá wa tukọ ìlànà náà ni Quickraiz ìtọ́ka wọn ni, https://quickraiz.com/campaign/323672-support-segun-oni-for-ekiti-2022 èyí náà sì ni ẹ ó rìí ní orí ìtàkùn àgbáyé àti àwọn ojú òpó ìkànsíra-ẹni wa. Mo mọ̀ pé nǹkan dagun lásìkò yìí. Èmi náà ní ìmọ̀lára rẹ̀. A gbọ́dọ̀ fìmọ̀ ṣọ̀kan láti jáwé olú borí nínú ètò Ìdìbò tó ń bọ̀ yìí.

Ẹ dákun, ẹ fi owó yín ràn wá lọ́wọ́, ẹ rí èyí gẹ́gẹ́ ẹbọ tí a gbọ́dọ̀ jọ rú láti mú kí Èkìtì di ńlá.

Àìsírètí ni ohun kan ṣoṣo tí fifi ààyè gba àwọn Olóṣèlú tó ti kùnà láti tẹ̀síwájú nípa rírọ́nà lọ yóò mú wá, èyí sì léwu púpọ̀ fún ìran yìí àti ìran tó ń bọ̀.

Láti ọwọ́ọ Onímọ̀-Ẹ̀rọ Ṣẹ́gun Òní